Native Bible

2 Chronicles 29:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ. Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́-àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.

2 Chronicles 29:22 in English

2 Chronicles 29:22 · Berean Standard Bible

So they slaughtered the bulls, and the priests took the blood and sprinkled it on the altar. They slaughtered the rams and sprinkled the blood on the altar. And they slaughtered the lambs and sprinkled the blood on the altar.

Context

20Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hesekiah sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa. 21Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Juda. Ọba pàṣẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, láti ṣe èyí lórí pẹpẹ Olúwa. 22Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ. Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́-àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ. 23Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. 24Àwọn àlùfáà wọn sì pa òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.