Native Bible

2 Chronicles 29:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hesekiah sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa.

2 Chronicles 29:20 in English

2 Chronicles 29:20 · Berean Standard Bible

Early the next morning King Hezekiah gathered the city officials and went up to the house of the LORD.

Context

18Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah láti lọ jábọ̀ fún un: “Àwa ti gbá ilé Olúwa mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò. 19A ti pèsè a sì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Ahasi ti sọ di aláìmọ́ nínú àìṣòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsin yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa.” 20Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hesekiah sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa. 21Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Juda. Ọba pàṣẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, láti ṣe èyí lórí pẹpẹ Olúwa. 22Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ. Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́-àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.