2 Kronika 29:17
2 Chronicles 29:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn sí i, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fúnra rẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ín-ní.
2 Chronicles 29:17 in English
2 Chronicles 29:17 · Berean Standard Bible
They began the consecration on the first day of the first month, and on the eighth day of the month they reached the portico of the LORD. For eight more days they consecrated the house of the LORD itself, finishing on the sixteenth day of the first month.
Context
15Nígbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ilé Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa. 16Àwọn àlùfáà sì wọ inú ilé Olúwa lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé Olúwa gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa. Àwọn ọmọ Lefi sì mú u wọ́n sì gbangba odò Kidironi. 17Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn sí i, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fúnra rẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ín-ní. 18Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah láti lọ jábọ̀ fún un: “Àwa ti gbá ilé Olúwa mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò. 19A ti pèsè a sì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Ahasi ti sọ di aláìmọ́ nínú àìṣòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsin yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.