2 Kronika 29:15
2 Chronicles 29:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ilé Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa.
2 Chronicles 29:15 in English
2 Chronicles 29:15 · Berean Standard Bible
When they had assembled their brothers and consecrated themselves, they went in to cleanse the house of the LORD, according to the command of the king by the words of the LORD.
Context
13nínú àwọn ọmọ Elisafani,
Ṣimri àti Jeieli;
nínú àwọn ọmọ Asafu,
Sekariah àti Mattaniah; 14nínú àwọn ọmọ Hemani,
Jehieli àti Ṣimei;
nínú àwọn ọmọ Jedutuni,
Ṣemaiah àti Usieli. 15Nígbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ilé Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa. 16Àwọn àlùfáà sì wọ inú ilé Olúwa lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé Olúwa gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa. Àwọn ọmọ Lefi sì mú u wọ́n sì gbangba odò Kidironi. 17Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn sí i, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fúnra rẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ín-ní.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.