2 Kronika 25:4
2 Chronicles 25:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn, olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
2 Chronicles 25:4 in English
2 Chronicles 25:4 · Berean Standard Bible
Yet he did not put their sons to death, but acted according to what is written in the Law, in the Book of Moses, where the LORD commanded: “Fathers must not be put to death for their children, and children must not be put to death for their fathers; each is to die for his own sin.”*
Context
2Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn. 3Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba. 4Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn, olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” 5Amasiah, pe gbogbo àwọn ènìyàn Juda pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún fún gbogbo Juda àti Benjamini, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì rí i pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú. 6Ó sì yá ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àwọn ọkùnrin oníjà láti Israẹli fún ọgọ́rùn-ún àwọn tálẹ́ǹtì fàdákà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.