Native Bible

2 Chronicles 25:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba.

2 Chronicles 25:3 in English

2 Chronicles 25:3 · Berean Standard Bible

As soon as the kingdom was firmly in his grasp, Amaziah executed the servants who had murdered his father the king.

Context

1Amasiah jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani, ó wá láti Jerusalẹmu. 2Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn. 3Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba. 4Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn, olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” 5Amasiah, pe gbogbo àwọn ènìyàn Juda pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún fún gbogbo Juda àti Benjamini, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì rí i pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.