Native Bible

2 Chronicles 25:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì yá ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àwọn ọkùnrin oníjà láti Israẹli fún ọgọ́rùn-ún àwọn tálẹ́ǹtì fàdákà.

2 Chronicles 25:6 in English

2 Chronicles 25:6 · Berean Standard Bible

He also hired 100,000 mighty warriors from Israel for a hundred talents of silver.*

Context

4Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn, olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” 5Amasiah, pe gbogbo àwọn ènìyàn Juda pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún fún gbogbo Juda àti Benjamini, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì rí i pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú. 6Ó sì yá ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àwọn ọkùnrin oníjà láti Israẹli fún ọgọ́rùn-ún àwọn tálẹ́ǹtì fàdákà. 7Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́ ogun láti Israẹli kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Israẹli kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Efraimu. 8Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Ọlọ́run ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.