Native Bible

2 Chronicles 23:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún.

2 Chronicles 23:9 in English

2 Chronicles 23:9 · Berean Standard Bible

Then Jehoiada the priest gave to the commanders of hundreds the spears and the large and small shields of King David that were in the house of God.

Context

7Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.” 8Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀. 9Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún. 10Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà. 11Jehoiada àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.