2 Kronika 23:7
2 Chronicles 23:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.”
2 Chronicles 23:7 in English
2 Chronicles 23:7 · Berean Standard Bible
The Levites must surround the king with weapons in hand, and anyone who enters the temple must be put to death. You must stay close to the king wherever he goes.”
Context
5Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa. 6Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítorí tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó sọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn. 7Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.” 8Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀. 9Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.