Native Bible

2 Chronicles 23:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà.

2 Chronicles 23:10 in English

2 Chronicles 23:10 · Berean Standard Bible

He stationed all the troops, with their weapons in hand, surrounding the king by the altar and the temple, from the south side to the north side of the temple.

Context

8Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀. 9Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún. 10Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà. 11Jehoiada àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!” 12Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.