2 Kronika 21:11
2 Chronicles 21:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.
2 Chronicles 21:11 in English
2 Chronicles 21:11 · Berean Standard Bible
Jehoram had also built high places on the hills of Judah; he had caused the people of Jerusalem to prostitute themselves and had led Judah astray.
Context
9Bẹ́ẹ̀ ni, Jehoramu lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Edomu yí i ká àti àwọn alákòóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì ṣẹ́gun wọn ní òru. 10Títí di ọjọ́ òní ni Edomu ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Juda.
Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jehoramu ti kọ Olúwa sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀. 11Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ. 12Jehoramu gba ìwé láti ọwọ́ Elijah wòlíì, tí ó wí pé,
“Èyí ní ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba à rẹ Dafidi wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jehoṣafati tàbí Asa ọba Juda. 13Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, ìwọ sì ti tọ́ Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé baba à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.