Native Bible

2 Chronicles 20:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé,

2 Chronicles 20:8 in English

2 Chronicles 20:8 · Berean Standard Bible

They have lived in the land and have built in it a sanctuary for Your Name, saying,

Context

6O sì wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. 7Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? 8Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, 9‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’ 10“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.