Native Bible

2 Chronicles 20:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’

2 Chronicles 20:9 in English

2 Chronicles 20:9 · Berean Standard Bible

‘If disaster comes upon us—whether sword or judgment,* plague or famine—we will stand before this temple and before You, for Your Name is in this temple. We will cry out to You in our distress, and You will hear us and save us.’

Context

7Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? 8Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, 9‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’ 10“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run. 11Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.