2 Kronika 19:6
2 Chronicles 19:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.
2 Chronicles 19:6 in English
2 Chronicles 19:6 · Berean Standard Bible
Then he said to the judges, “Consider carefully what you do, for you are not judging for man, but for the LORD, who is with you when you render judgment.
Context
4Jehoṣafati sì ń gbé ní Jerusalẹmu ó sì jáde lọ padà láàrín àwọn ènìyàn láti Beerṣeba dé òkè ìlú Efraimu, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn. 5Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda. 6Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́. 7Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” 8Ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, Jehoṣafati yan díẹ̀ lára àwọn Lefi, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Israẹli si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.