Native Bible

2 Chronicles 19:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda.

2 Chronicles 19:5 in English

2 Chronicles 19:5 · Berean Standard Bible

He appointed judges in the land, in each of the fortified cities of Judah.

Context

3Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà Aṣerah kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run.” 4Jehoṣafati sì ń gbé ní Jerusalẹmu ó sì jáde lọ padà láàrín àwọn ènìyàn láti Beerṣeba dé òkè ìlú Efraimu, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn. 5Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda. 6Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́. 7Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.