Native Bible

2 Chronicles 18:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà. Wọ́n sì wí pé, “Dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

2 Chronicles 18:11 in English

2 Chronicles 18:11 · Berean Standard Bible

And all the prophets were prophesying the same, saying, “Go up to Ramoth-gilead and prosper, for the LORD will deliver it into the hand of the king.”

Context

9Wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn, ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu-bodè Samaria, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 10Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.’ ” 11Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà. Wọ́n sì wí pé, “Dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” 12Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.” 13Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa ń bẹ láààyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.