Native Bible

2 Chronicles 18:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.’ ”

2 Chronicles 18:10 in English

2 Chronicles 18:10 · Berean Standard Bible

Now Zedekiah son of Chenaanah had made for himself iron horns and declared, “This is what the LORD says: ‘With these you shall gore the Arameans until they are finished off.’”

Context

8Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹ mú Mikaiah ọmọ Imla kí ó yára wá.” 9Wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn, ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu-bodè Samaria, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 10Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.’ ” 11Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà. Wọ́n sì wí pé, “Dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun, nítorí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” 12Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.