2 Kronika 14:5
2 Chronicles 14:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Juda. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀.
2 Chronicles 14:5 in English
2 Chronicles 14:5 · Berean Standard Bible
He also removed the high places and incense altars from all the cities of Judah, and under him the kingdom was at peace.
Context
3Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga. Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn ère Aṣerah bolẹ̀. 4Ó pa á láṣẹ fún Juda láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ. 5Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Juda. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀. 6Ó mọ àwọn ìlú ààbò ti Juda, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lú rẹ̀ nígbà náà, nítorí Olúwa fún un ní ìsinmi. 7“Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí,” ó wí fún Juda, “kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ilé ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu-ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.