2 Kronika 14:7
2 Chronicles 14:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí,” ó wí fún Juda, “kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ilé ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu-ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.
2 Chronicles 14:7 in English
2 Chronicles 14:7 · Berean Standard Bible
So he said to the people of Judah, “Let us build these cities and surround them with walls and towers, with doors and bars. The land is still ours because we have sought the LORD our God. We have sought Him and He has given us rest on every side.” So they built and prospered.
Context
5Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Juda. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀. 6Ó mọ àwọn ìlú ààbò ti Juda, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lú rẹ̀ nígbà náà, nítorí Olúwa fún un ní ìsinmi. 7“Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí,” ó wí fún Juda, “kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ilé ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu-ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere. 8Asa ní àwọn ọmọ-ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin láti Juda. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) láti Benjamini wọ́n dira pẹ̀lú àwọn àpáta kéékèèké àti àwọn ọrun. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin. 9Sera ará Etiopia yàn láti dojúkọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Meraṣa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.