2 Kronika 13:2
2 Chronicles 13:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah. Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu.
2 Chronicles 13:2 in English
2 Chronicles 13:2 · Berean Standard Bible
and he reigned in Jerusalem three years. His mother’s name was Micaiah * daughter * of Uriel; she was from Gibeah. And there was war between Abijah and Jeroboam.
Context
1Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jeroboamu, Abijah di ọba Juda. 2Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah.
Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. 3Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára. 4Abijah dúró lórí òkè Semaraimu ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, ó sì wí pé, Jeroboamu àti gbogbo Israẹli, ẹ gbọ́ mi!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.