2 Kronika 13:17
2 Chronicles 13:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Abijah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdààmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Israẹli.
2 Chronicles 13:17 in English
2 Chronicles 13:17 · Berean Standard Bible
Then Abijah and his people struck them with a mighty blow, and 500,000 chosen men of Israel fell slain.
Context
15Olúkúlùkù, ọkùnrin Juda sì fún ìpè ogun, ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Juda sì ti fun ìpè ogun, ni Ọlọ́run kọlu Jeroboamu àti gbogbo Israẹli níwájú Abijah àti Juda. 16Àwọn ọmọ Israẹli sálọ kúrò níwájú Juda, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́. 17Abijah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdààmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Israẹli. 18Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Juda sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn. 19Abijah sì lépa Jeroboamu, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Beteli pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣana pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Efroni pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.