1 Timotiu 3:9
1 Timothy 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun.
1 Timothy 3:9 in English
1 Timothy 3:9 · Berean Standard Bible
They must hold to the mystery of the faith with a clear conscience.
Context
7Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má ba à bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ̀kùn èṣù. 8Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò. 9Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun. 10Kí a kọ́kọ́ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn. 11Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.