Native Bible

1 Timothy 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo.

1 Timothy 3:11 in English

1 Timothy 3:11 · Berean Standard Bible

In the same way, the women * must be dignified, not slanderers, but temperate and faithful in all things.

Context

9Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun. 10Kí a kọ́kọ́ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn. 11Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo. 12Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára. 13Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.