Native Bible

1 Samuel 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.”

1 Samuel 9:8 in English

1 Samuel 9:8 · Berean Standard Bible

The servant answered him again. “Look,” he said, “I have here in my hand a quarter shekel of silver.* I will give it to the man of God, and he will tell us our way.”

Context

6Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ síbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a yóò gbà.” 7Saulu sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?” 8Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.” 9(Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì). 10Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára, “Jẹ́ kí a lọ.” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.