1 Samuẹli 9:10
1 Samuel 9:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára, “Jẹ́ kí a lọ.” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.
1 Samuel 9:10 in English
1 Samuel 9:10 · Berean Standard Bible
“Good,” said Saul to his servant. “Come, let us go.” So they set out for the city where the man of God was.
Context
8Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.” 9(Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì). 10Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára, “Jẹ́ kí a lọ.” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé. 11Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí. Wọ́n sì bi wọ́n, “Ṣé wòlíì náà wà níbí?” 12“Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsin yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.