Native Bible

1 Samuel 30:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sọkún.

1 Samuel 30:4 in English

1 Samuel 30:4 · Berean Standard Bible

So David and the troops with him lifted up their voices and wept until they had no strength left to weep.

Context

2Wọ́n sì kó àwọn obìnrin tí ń bẹ nínú rẹ̀ ní ìgbèkùn, wọn kò sì pa ẹnìkan, ọmọdé tàbí àgbà, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ. 3Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin sì wọ ìlú Siklagi, sì wò ó, a ti kùn ún ni iná; àti obìnrin wọn, àti ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn ni a kó ni ìgbèkùn lọ. 4Dafidi àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sọkún. 5A sì kó àwọn aya Dafidi méjèèjì nígbèkùn lọ, Ahinoamu ará Jesreeli àti Abigaili aya Nabali ará Karmeli. 6Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.