Native Bible

1 Samuel 30:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

1 Samuel 30:6 in English

1 Samuel 30:6 · Berean Standard Bible

And David was greatly distressed because the people spoke of stoning him, because the soul of every man grieved for his sons and daughters. But David found strength in the LORD his God.

Context

4Dafidi àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sọkún. 5A sì kó àwọn aya Dafidi méjèèjì nígbèkùn lọ, Ahinoamu ará Jesreeli àti Abigaili aya Nabali ará Karmeli. 6Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 7Dafidi sì wí fún Abiatari àlùfáà, ọmọ Ahimeleki pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú efodu fún mi wá níhìn-ín yìí. Abiatari sì mú efodu náà wá fún Dafidi. 8Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa, nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.