Native Bible

1 Samuel 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘Máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

1 Samuel 3:9 in English

1 Samuel 3:9 · Berean Standard Bible

“Go and lie down,” he said to Samuel, “and if He calls you, say, ‘Speak, LORD, for Your servant is listening.’” So Samuel went and lay down in his place.

Context

7Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án. 8Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.” Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. 9Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘Máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀. 10Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!” Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.” 11Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.