Native Bible

1 Samuel 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

1 Samuel 3:7 in English

1 Samuel 3:7 · Berean Standard Bible

Now Samuel did not yet know the LORD, because the word of the LORD had not yet been revealed to him.

Context

5Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.” Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀. 6Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.” “Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.” 7Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án. 8Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.” Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. 9Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘Máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.