Native Bible

1 Samuel 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.” “Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

1 Samuel 3:6 in English

1 Samuel 3:6 · Berean Standard Bible

Once again the LORD called, “Samuel!” So Samuel got up, went to Eli, and said, “Here I am, for you have called me.” “My son, I did not call,” Eli replied. “Go back and lie down.”

Context

4Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli. Samuẹli sì dáhùn, “Èmi nìyí.” 5Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.” Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀. 6Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.” “Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.” 7Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án. 8Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.” Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.