Native Bible

1 Samuel 28:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.

1 Samuel 28:18 in English

1 Samuel 28:18 · Berean Standard Bible

Because you did not obey the LORD or carry out His burning anger against Amalek, the LORD has done this to you today.

Context

16Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀. 17Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi. 18Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí. 19Olúwa yóò sì fi Israẹli pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filistini lọ́wọ́, ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Israẹli lé àwọn Filistini lọ́wọ́.” 20Lójúkan náà ni Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja níbí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Samuẹli; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà tọ̀sán tòru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.