1 Samuẹli 28:17
1 Samuel 28:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi.
1 Samuel 28:17 in English
1 Samuel 28:17 · Berean Standard Bible
He has done exactly what He spoke through me: The LORD has torn the kingship out of your hand and given it to your neighbor David.
Context
15Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?”
Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.” 16Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀. 17Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi. 18Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí. 19Olúwa yóò sì fi Israẹli pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filistini lọ́wọ́, ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Israẹli lé àwọn Filistini lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.