1 Samuẹli 28:15
1 Samuel 28:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?” Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”
1 Samuel 28:15 in English
1 Samuel 28:15 · Berean Standard Bible
Then Samuel said to Saul, “Why have you disturbed me by bringing me up?” “I am deeply distressed,” replied Saul. “The Philistines are fighting against me, and God has turned away from me. He no longer answers me, either by prophets or by dreams. So I have called on you to tell me what to do.”
Context
13Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?”
Obìnrin náà sì wí fún Saulu pé, “Èmi rí ọlọ́run kan tí ń ti ilẹ̀ wá.” 14Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.”
Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.”
Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀. 15Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?”
Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.” 16Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀. 17Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.