Native Bible

1 Samuel 28:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.” Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.” Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.

1 Samuel 28:14 in English

1 Samuel 28:14 · Berean Standard Bible

“What does he look like?” asked Saul. “An old man is coming up,” she replied. “And he is wearing a robe.” So Saul knew that it was Samuel, and he bowed facedown in reverence.

Context

12Nígbà tí obìnrin náà sì rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Saulu sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Saulu ni ìwọ jẹ́.” 13Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?” Obìnrin náà sì wí fún Saulu pé, “Èmi rí ọlọ́run kan tí ń ti ilẹ̀ wá.” 14Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.” Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.” Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀. 15Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?” Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.” 16Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.