1 Samuẹli 28:20
1 Samuel 28:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lójúkan náà ni Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja níbí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Samuẹli; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà tọ̀sán tòru.
1 Samuel 28:20 in English
1 Samuel 28:20 · Berean Standard Bible
Immediately Saul fell flat on the ground, terrified by the words of Samuel. And his strength was gone, because he had not eaten anything all that day and night.
Context
18Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí. 19Olúwa yóò sì fi Israẹli pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filistini lọ́wọ́, ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Israẹli lé àwọn Filistini lọ́wọ́.” 20Lójúkan náà ni Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja níbí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Samuẹli; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà tọ̀sán tòru. 21Obìnrin náà sì tọ Saulu wá, ó sì rí i pé ó wà nínú ìbànújẹ́ púpọ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó, ìránṣẹ́bìnrin rẹ́ ti gbọ́ ohun rẹ̀, èmi sì ti fi ẹ̀mí mi sí ọwọ́ mi, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ti ìwọ sọ fún mi. 22Ǹjẹ́, nísinsin yìí èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi yóò sì fi oúnjẹ díẹ̀ síwájú rẹ̀; sì jẹun, ìwọ yóò sì lágbára, nígbà tí ìwọ bá ń lọ lọ́nà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.