Native Bible

1 Samuel 27:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali.

1 Samuel 27:3 in English

1 Samuel 27:3 · Berean Standard Bible

David and his men settled in Gath with Achish. Each man had his family with him, and David had his two wives: Ahinoam of Jezreel and Abigail of Carmel, the widow of Nabal.

Context

1Dafidi sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Saulu ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Filistini, yóò sú Saulu láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbègbè Israẹli, èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.” 2Dafidi sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati. 3Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali. 4A sì sọ fún Saulu pé, Dafidi sálọ si Gati, òun kò sì tún wá á kiri mọ́. 5Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀, èéṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.