Native Bible

1 Samuel 27:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀, èéṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

1 Samuel 27:5 in English

1 Samuel 27:5 · Berean Standard Bible

Then David said to Achish, “If I have found favor in your eyes, let me be assigned a place in one of the outlying towns, so I can live there. For why should your servant live in the royal city with you?”

Context

3Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali. 4A sì sọ fún Saulu pé, Dafidi sálọ si Gati, òun kò sì tún wá á kiri mọ́. 5Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀, èéṣe tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.” 6Akiṣi sí fi Siklagi fún un ní ọjọ́ náà nítorí náà ni Siklagi fi dí ọba Juda títí ó fi dì òní yìí. 7Iye ọjọ́ tí Dafidi fi jókòó ní ìlú àwọn Filistini sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.