1 Samuẹli 27:1
1 Samuel 27:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Saulu ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Filistini, yóò sú Saulu láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbègbè Israẹli, èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”
1 Samuel 27:1 in English
1 Samuel 27:1 · Berean Standard Bible
David, however, said to himself, “One of these days now I will be swept away by the hand of Saul. There is nothing better for me than to escape to the land of the Philistines. Then Saul will stop searching for me all over Israel, and I will slip out of his hand.”
Context
1Dafidi sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Saulu ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Filistini, yóò sú Saulu láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbègbè Israẹli, èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.” 2Dafidi sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati. 3Dafidi sì bá Akiṣi jókòó ní Gati, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dafidi pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili ará Karmeli aya Nabali.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.