Native Bible

1 Samuel 27:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.”

1 Samuel 27:10 in English

1 Samuel 27:10 · Berean Standard Bible

who would ask him, “What have you raided today?” And David would reply, “The Negev of Judah,” or “The Negev of Jerahmeel,” or “The Negev of the Kenites.”

Context

8Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti. 9Dafidi sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láààyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ìbákasẹ, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Akiṣi wá. 10Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.” 11Dafidi kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láààyè, láti mú ìròyìn wá sí Gati, wí pé, “Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa níbẹ̀, pé, ‘Báyìí ni Dafidi ṣe,’ ” àti bẹ́ẹ̀ ni ìṣe rẹ̀, yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fi jókòó ni ìlú àwọn Filistini. 12Akiṣi sì gba ti Dafidi gbọ́, wí pé, “Òun ti mú kí Israẹli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kórìíra rẹ̀ pátápátá, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.