1 Samuẹli 27:8
1 Samuel 27:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti.
1 Samuel 27:8 in English
1 Samuel 27:8 · Berean Standard Bible
Now David and his men went up and raided the Geshurites, the Girzites, and the Amalekites. (From ancient times these people had inhabited the land extending to Shur and Egypt.)
Context
6Akiṣi sí fi Siklagi fún un ní ọjọ́ náà nítorí náà ni Siklagi fi dí ọba Juda títí ó fi dì òní yìí. 7Iye ọjọ́ tí Dafidi fi jókòó ní ìlú àwọn Filistini sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin. 8Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Geṣuri, àti àwọn ará Gesri, àti àwọn ará Amaleki àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣuri títí ó fi dé ilẹ̀ Ejibiti. 9Dafidi sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láààyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ìbákasẹ, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Akiṣi wá. 10Akiṣi sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dafidi sì dáhùn pé, “Sí ìhà gúúsù ti Juda ni, tàbí sí ìhà gúúsù ti Jerahmeeli,” tàbí “Sí ìhà gúúsù ti àwọn ará Keni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.