Native Bible

1 Samuel 25:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”

1 Samuel 25:41 in English

1 Samuel 25:41 · Berean Standard Bible

She arose, then bowed facedown and said, “Here is your maidservant, ready to serve and to wash the feet of my lord’s servants.”

Context

39Dafidi sì gbọ́ pé Nabali kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbèjà gígàn mi láti ọwọ́ Nabali wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ìkà Nabali sí orí òun tìkára rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́, ó sì ba Abigaili sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀. 40Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì lọ sọ́dọ̀ Abigaili ni Karmeli, wọn sì sọ fún un pé, “Dafidi rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.” 41Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.” 42Abigaili sì yára, ó sì dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ márùn-ún sì tẹ̀lé e lẹ́yìn; òun sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, o sì wá di aya rẹ̀. 43Dafidi sì mú Ahinoamu ará Jesreeli; àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.