Native Bible

1 Samuel 25:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì gbọ́ pé Nabali kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbèjà gígàn mi láti ọwọ́ Nabali wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ìkà Nabali sí orí òun tìkára rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́, ó sì ba Abigaili sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.

1 Samuel 25:39 in English

1 Samuel 25:39 · Berean Standard Bible

On hearing that Nabal was dead, David said, “Blessed be the LORD, who has upheld my cause against the reproach of Nabal and has restrained His servant from evil. For the LORD has brought the wickedness of Nabal down upon his own head.” Then David sent word to Abigail, asking for her in marriage.

Context

37Ó sì ṣe; ni òwúrọ̀, nígbà ti ọtí náà si dá tán lójú Nabali, obìnrin rẹ̀ sì ro nǹkan wọ̀nyí fún un, ọkàn rẹ sì kú nínú rẹ̀, òun sì dàbí òkúta. 38Ó sì ṣe lẹ́yìn ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́wàá, Olúwa lu Nabali, ó sì kú. 39Dafidi sì gbọ́ pé Nabali kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbèjà gígàn mi láti ọwọ́ Nabali wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ìkà Nabali sí orí òun tìkára rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́, ó sì ba Abigaili sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀. 40Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì lọ sọ́dọ̀ Abigaili ni Karmeli, wọn sì sọ fún un pé, “Dafidi rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.” 41Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.