1 Samuẹli 24:17
1 Samuel 24:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ.
1 Samuel 24:17 in English
1 Samuel 24:17 · Berean Standard Bible
and said to David, “You are more righteous than I, for you have rewarded me with good, though I have rewarded you with evil.
Context
15Kí Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.” 16Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. 17Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. 18Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, ìwọ kò sì pa mí. 19Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.