1 Samuẹli 24:16
1 Samuel 24:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún.
1 Samuel 24:16 in English
1 Samuel 24:16 · Berean Standard Bible
When David had finished saying these things, Saul called back, “Is that your voice, David my son?” Then Saul wept aloud
Context
14“Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? 15Kí Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.” 16Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. 17Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. 18Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, ìwọ kò sì pa mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.