1 Samuẹli 22:16
1 Samuel 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”
1 Samuel 22:16 in English
1 Samuel 22:16 · Berean Standard Bible
But the king replied, “You will surely die, Ahimelech, you and all your father’s house!”
Context
14Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ. 15Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.” 16Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.” 17Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.”
Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n. 18Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.