Native Bible

1 Samuel 22:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.

1 Samuel 22:17 in English

1 Samuel 22:17 · Berean Standard Bible

Then the king ordered the guards at his side, “Turn and kill the priests of the LORD, because they too sided with David. For they knew he was fleeing, but they did not tell me.” But the king’s servants would not lift a hand to strike the priests of the LORD.

Context

15Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.” 16Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.” 17Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n. 18Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu. 19Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.