1 Samuẹli 21:2
1 Samuel 21:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.
1 Samuel 21:2 in English
1 Samuel 21:2 · Berean Standard Bible
“The king has given me a mission,” David replied. “He told me no one is to know about the mission or charge. And I have directed my young men to meet me at a certain place.
Context
1Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?” 2Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí. 3Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.” 4Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́. Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.