Native Bible

1 Samuel 21:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?”

1 Samuel 21:1 in English

1 Samuel 21:1 · Berean Standard Bible

Then David came to Nob, to Ahimelech the priest. And when Ahimelech met David, he trembled and asked him, “Why are you alone? Why is no one with you?”

Context

1Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?” 2Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí. 3Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.