1 Samuẹli 18:9
1 Samuel 18:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlara wo Dafidi.
1 Samuel 18:9 in English
1 Samuel 18:9 · Berean Standard Bible
And from that day forward Saul kept a jealous eye on David.
Context
7Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé,
“Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀
Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárún ní tirẹ̀.” 8Saulu sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dafidi pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárún,” ó sì wí pé, “ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?” 9Láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlara wo Dafidi. 10Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Saulu, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dafidi sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Saulu sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀. 11Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dafidi pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dafidi yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.