1 Samuẹli 17:16
1 Samuel 17:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún ogójì ọjọ́, Filistini wá síwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.
1 Samuel 17:16 in English
1 Samuel 17:16 · Berean Standard Bible
For forty days the Philistine came forward every morning and evening to take his stand.
Context
14Dafidi ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Saulu, 15ṣùgbọ́n Dafidi padà lẹ́yìn Saulu, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu. 16Fún ogójì ọjọ́, Filistini wá síwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn. 17Nísinsin yìí Jese wí fún ọmọ rẹ̀ Dafidi pé, “Mú ìwọ̀n efa àti àgbàdo yíyan àti ìṣù àkàrà mẹ́wàá lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ kí o sì súré lọ sí ibùdó o wọn. 18Kí o sì mú wàrà mẹ́wàá yìí lọ́wọ́ fún adarí ogun tiwọn. Wo bí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe wà kí o sì padà wá fún mi ní àmì ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.